Luke 22:63-71

Àwọn ẹ̀ṣọ́ n gan Jesu

63 aÓ sì ṣe, àwọn ọkùnrin tí wọ́n mú Jesu, sì fi í ṣe ẹlẹ́yà, wọ́n lù ú. 64Nígbà tí wọ́n sì dì í ní ojú, wọ́n lù ú níwájú, wọ́n ń bi í pé, “Sọtẹ́lẹ̀! Ta ni ó lù ọ́?” 65Wọ́n sì sọ ọ̀pọ̀ ohun búburú mìíràn sí i, láti fi ṣe ẹlẹ́yà.

Jesu níwájú Pilatu àti Herodu

66 bNígbà tí ilẹ̀ sì mọ́, ìjọ àwọn alàgbà àwọn ènìyàn péjọpọ̀, àti àwọn olórí àlùfáà, àti àwọn akọ̀wé, wọ́n sì fà á lọ sí àjọ wọn, wọ́n ń wí pé, 67 c“Bí ìwọ bá jẹ́ Kristi náà? Sọ fún wa!”

Ó sì wí fún wọn pé, “Bí mo bá wí fún yín, ẹ̀yin kì yóò gbàgbọ́;
68Bí mo bá sì bi yín léèrè pẹ̀lú, ẹ̀yin kì yóò dá mi lóhùn, (bẹ́ẹ̀ ni ẹ kì yóò fi mí sílẹ̀ lọ). 69Ṣùgbọ́n láti ìsinsin yìí lọ ni Ọmọ ènìyàn yóò jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún agbára Ọlọ́run.”

70 dGbogbo wọn sì wí pé, “Ìwọ ha ṣe Ọmọ Ọlọ́run bí?”

Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin wí pé, èmi ni.”

71Wọ́n sì wí pé, “Ẹ̀rí wo ni àwa tún ń fẹ́ àwa tìkára wa sá à ti gbọ́ lẹ́nu rẹ̀!”

Copyright information for YorBMYO